كلمات Mabanuje
Kilode
Omo iya mi kilode to fin nbanuje
Se nitori oun to fe je
Jowo mowo kuro leran
Walahi o da mi loju , wa pada je
Oun to fin ro nu, o o se poba to nje?
Titobi re Oba ta npe to nje
Awon kan nsukun airo nje je
Awon kan tun ni , ko sa laafia ti won o fi je
Won se se tun mon bee won ki won o to le je e
Won a ni lagbaja, dakun rooju jeun
Jalah jalaluhu olohun Oba ejee
Se bawon kan ni won tun fegba fun lounje je
Kaiye ma fegba femi lounje je
Aimoye eyan taye won ti baje
Nitori oun ti won fe je
Olohun dakun MO bayemi je
Tori won ni ti tenikan o ba baje
Tenikan o le da, se nitori oun to fe je
Iwo wa nbanu je, nitori oun to fe je
Odami loju pe gbogbo oun to nba e ninu je
Laipe lai jinna, ekun re o dayo, mobara je
Adura o ta e nipe kori ibanuje o
Iwo sati sunmo olohun, o damiloju pe wa a pada je
Omo iyami MO banuje e
Aboti gbagbe pe leyin ibanuje
Idunnu loku o se jeje
Anobi Muhammadu to je ore olohun, o ri banuje
Sibe sibe anabi o baraje
Awa ta o wa je nkankan kilode ta o se jeje ooo
Omo iyami tiwo barije fomo lakeji re je
Tori to oun na ba pada wa ni, koni gbagbee pe
Oti fo unje ma yalada je
Ta leyin tun npe laje, taleni tan pe ti o ni je
Iwo nba tomo lakeji je, ode fe kaiye ti e ooo baje oo
Kiloferi nibi ko ba tomo lakeji je
Eje ka lo jawo nibi ibaje ooo
Toripe gbogbo ori ko lo se yanje ee
Oun toni kaluku ma je, olohun ti ko o
Walahi a o pada je
Oko Iyawo se jeje o, Iwo Iyawo se jeje o
Tori won nba e so, o so pʼolohun ma ma je o
Iwa e loma determine oun to ma je
MO kole ogun, mo ra motor ogbon
Ile naa ni o pada je ee
MJ loruko mi!!